OJU LOGE

Yoruba bo, won ni, Ori nigbe alawore kooni, awon na lo tun buse gada, ti won so wipe, Oju ni atokun ara. Oju lo’ge looto, sugbon kini itumo Oju lo’ge.

 

Ni ile Yoruba, Oge sise bere lati ibi itoju oju, bi okunrun ba ri akoyinsi obinrin, ko si bo tile se rewa to la’teyin, ‘’bawo ni oju re seeri gann? ni ibere ti yo te le. Nigba ti oju nbe lorokun, awon iya wa a se imo toto oju, won a dirun adimole olowo, bi won ba ri okunrin, won mo’ju gbeere, won a fi owo geresi aso buba won nibi orun. Okunrin a tun won wo le’keji…’Hmm, Obinrin lo rewa to yi’.

 

Yoruba a tun ma da lasa,,,won a ni, ‘oju lagbere wa’. Bi oju okunrin ati obinrin ba se merin, ti obinrin ba gboju sa larin iseju aya, o ni itumo, sugbon ti o ba wo o sun-sun-sun fun igba pipe, haa! Ore mi, okete ti bo’ru mo o lowo. Yoruba kanna lo tun so wipe ‘ Oju loro wa’. Bi okunrin ban ni gbolohun ife pelu arewa obinrin ni ile ‘Kaaro o jiire’, bi obinrin ba n wo ile, aponle ni!, okunrin a ni ‘’ Asake, woju mi’’ Hmm, alakori fe mo idahun si gbogbo atotonu ti o tin so ni o, lati ibi eyinju Asake.

 

Itoju oju ati gbogbo ara lo se pataki ju ile Yoruba. Ewa ede ati aponle si po ninu ede naa, bo ba pupa foo, Yoruba a ni ‘amolewa bi ododo, boosi dudu, won a ni ‘ o dudu bi koro isin’, iwo gbiyanju ko kuru, akuru ye’jo ni o. Obinrin ti ko lara pupo to si ga niwontun-wonsi ni Yoruba npe ni ‘osoro olomoge’, a gaga bi o ba lomi lara, won a ni ‘ ewo idi ileke, o ri runmu-runmu’.

 

E jo, Yoruba lo la’sa!


Comments