AWON OUNJE ILE YORUBA.




                               *EBA: Eba je ounje Pataki ni ile Yoruba ati kaakakiri. O je ounje ti a maa n saba je ni ile Yoruba ko si omo bibi ile Yoruba to le se lai je eba laarin ojo meji.orisirisi obe bii obe efo,gbegiri,ebolo tabi obe eeyi ti o wu yin.

*IRESI: hnmmmm……..iresi je ounje to se Pataki ju ni gbogbo agbaye.bi won tii pe ni iresi ni ile alawo dudu naa ni awon won se n je ni ile alawo funfun  ti won sii n fi enu felefele pe ni RICE.bi a ba fe pa tan ki a din ata dindin ki awa fi igbin eja gbigbe foo lori.hnmmm…….ounje tii sooo
*LAFUN:Lafun je ounje to wopo ju laarin awon ara egba .onje okele ni lafun je aromora sii ni pelu.A le fi orisirisi obe je sugbon obe ti o tayo julo pelu re ni obe gbure oloboro ati eran tabi eja a si le fii gbonmo gbe sofun.
*IYAN:awon Yoruba a maa so wipe iyan to wewu egusi,to de fila isapa hnnmmm…….I-Y-A-N. a baa lowo awon baba nla wa o si je ounje  to gbayi julo nile Yoruba.isu lama gun felefele ninu odo titi yo fi di iyan a le fi isapa je tabi obe egusi sugbon obe to tayo julo ni obe efo elegusi tabi riro ki a wa fi  eran igbe de lade.a le fi emu ogidi sin losale.
*SAPALA: Hnmm….sapala elepo…odun yenyen.sapala je okan lara ounje Yoruba ,o jo moin-moin pupo sugbon  agbado pelu ata ati epo pupa ni a fii ma n se sapala.awon elomiran a maa je lasan awon miiran a si ma mu gaari olomi tutu peli re.
*IKOKORE:Ikokore je ounje to gbajumo laarin awon ara ijebu.isu ewura ,ata,epo ati awon eronja bii ede,eja la ma fin n se ikokore yii  a si le je pelu eba tabi okele tomba wun nii.
*EBIRIPO:Ebiripo je onje to se koko fun awon ara ijebu.isu koko ni a ma fi n se ebiripo a sii pon sinu ewe sori ina bii eni pon moin-moin.obe eyikeyi to ba wuni nii na fi n tii sonafun.
*ASARO:Asaro elepo je ounje to gbayii laarin gbogbo omo ile kaaro-o-jiire.Ako isu pelu epo pupa ati ata,eja ni a maa fi n se Asaro .aropo sii lama fii se ni ori ina.a le fi omi tutu tabi oti olomi osan tee lo si ona ofun.
*EGBO:Egbo je okan lara ounje ile Yoruba.Agbado funfunni a o se lasero petepete.a le je pelu ata dindin tabi ki a fi ororo yii pelu ewa aganyin.
*OFADA:Ofada je iresi ile Yoruba ti o sii maa n muni  datami.ile Yoruba nii a ti n gbin a sii ma se bii eni se iresi gangan.Ata dindin to ta lenu sue-sue pelu awon eronja bii igbin,eja gbigbe pelu eran tabi ponmo dee lade.
*EWA AGANYIN:Ewa aganyin naa wa lara ounje to se koko ni ile Yoruba.a o se ewa naa lasero ti yo fo petepete.a o wa din ata re ni adin dudu. O dara pelu boogan tabi isu bibo tabi dindin.
*MOIN-MOIN:Moyin-moyin….ounje to wuyi ni ile Yoruba.ewa lilo ni a fi n se moin-moin bi a ba fe wa pa kuu, ki awa lo run ede ati eja osan sinu re ki a si wa fi ewe pon sori ina.haaa….ounje deee.a le fi buredi, ogi,eko tii sofun.
*PUPURU(FUFU):pupuru  dabi fufu,ile ondo ni a maa ti n saba jee. Iyato to wa laarin oun ati fufu ni wipe a maa n yan pupuru lori ina nii.a sii le je pelu obe ila alasepo
*AKARA ELEPO:Akara elepo wa lara ounje to fajumora ni ile Yoruba.Ewa, ata, ni a o loo pelu alubosa lati fii mu adun re po yoyo, a o wa din lori ina pelu epo pupa. A le je pelu eko,boogan tabi ki a mu pelu gaari olomi tutu.
*EWA ADARU:Ewa adaru naa je okan lara ounje ile Yoruba ti o dun ti o si fajumora.Ewa ati agbado ni a maa n se papo lori ina ti a si ma n fi epo  pupa dabira sii loju.gaari lebu lo fakoyo pelu ree .
*OFULOJU:Ofuloju je okan lra ounje Yoruba to gbamuse.ewa funfun pelu alubossa nikan la o lo ti a o sip on sinu ewe lori ina.a o wa fi ata dindin ti a ti fi orisirisi eronja ge fila le lori
*EMOOYO:Emooyo je obe fun awon ara eko.eja tutu ni a ma fi n se obey ii a si le fi je okele eyikeyi ti o ba wun nii.
*EWA ATI DODO:Ewa ati dodo je ounje Yoruba ti o fojumora pupo.a o se ewa,a o wa da dodo dindin tabi bibo lee.a le je lasan a si le je pelu boogan.
*ISU SISUN ATI EPO:A ba ninu itan mo aroba wipe awon agbe ni won koko bere sini je iru ounje yii nigba tie bi ba n pa won loko,won a ya mu isu sun won a si gba epo pupa tabi ki won je pelu epo bee.nisinyi o ti di okan lara ounje Yoruba to gbajumo.   

Comments