IWURE OWURO

Iba Akoda,Iba Aseda
Iba fun gbogbo awon ti o ni ile aiye

Ka ji ni kutukutu
Ka mu ohun ipin ko’pin
d'Ifa fun Olomo-ajiba’re-pade
Emi ni mo ji ni kutukutu ti mo f’ohun ipin ko’pin
Emi ni mo ba ire pade l’ola

Iba eyin iyami olokiki oru aperan mapagun ojani masia
Owo popo lafi n'wo igi
Owo orisa ni won fi n'wo igbin
Oun na tu'ni afi n'wo afin
Aki fi alagemo sagbo
Kafi orisa miran sojuagbo
Aki fi eyin adie s'oko
Oso ilu e'fun mi l'owo mi
Aje ilu e'fun mi l'owo mi
Omode ilu temi ni ese
Agbagba ilu temi ni ese
Teru t'omon lon wo iran agiliti

Nitori wipe kinni?......
Oju ni gbayi lowo Ori,
Ese ni gbayi lowo ona,
Aso funfun ni gbayi lara oku
...... Ki a ma gbayi lowo aje ile. oso ile, lebo logun,
Okunrin oun t'obirin, l'omode oun t'agba.

Awise ni ti Ifa
Afose ni ti Orunmila Baba Agbonmiregun.

Comments