Adewale Ayuba ti
gbogbo eniyan mo si “AYUBA” ni a bi ni ojo kefa ,osu karun odun 1966 si ilu
ikenne remo, ipinle ogun,naijiria.o
bere orin kiko lati igba ewe re nib ii
omo odun mejo ti o si n ko orin kaakakiri fun idije orin ni ilu ikenne remo. O
je onkorin fuji to yato gedengbe pelu orin fuji to ma n da awon olowo,gbajumo
ati awon eeyan yepere lawujo lorun ni ile naijiria ati loke okun.o yato si awon
onkorin egbe re nitori o kawe gboye.O ni diploma ni ogun state polytechnic ati
advance diploma ni university of lagos 9pelu
associate degree lati
Queenborough community college ni ile new York ati
degree ninu PH.D
ti o si n duro. Oun ni onkorin akoko
ati onkorin fuji ti yo koko gba ami eye KORA nigba ti o gba ami eye
meji lati owo KORAni odun 2005ati ajosepo pelu onkorin naijiria to n gbe ni oke
okun,ADE BANTU.Ayuba feran lati maa ka iwe pupo o si ni awon onkorin repete
bii FELA,K.S.A,I.K DAIRO,EBENEZER
OBEY,AYINDE BARRISTER,KOLLINGHTON AYINLA,HARUNA ISHOLA,ORLANDO OWOH, pelu awon
gbajumo onkorin lati oke okun bii BOB MARLEY ATI CELINE DION gege bii awokose.
Awo
orin akoko ti ayuba yoo koko se ni IBERE.Awo orin yii jade lati owo success
record ni aarin odun 1980 pelu aseyori ti ko kun oju osuwon.Leyin awo orin bii
mefa ti ko mu aseyori rere jade,Ayuba pelu
alabojuto ise re te siwaju lati lo se iwadi oun titun.
Nigba
to di 1989,shina peters je olorin ti o lo nigbiro ti okiki re si nkan
nigbana,awon okunrin meji yii da eda fuji tuntun imi sile ti o si farajo iru awo orin shina peters.Gege bii iwadi,Aderohunmu da laba fun Ayuba wipe
ti o ba fe se ori ire, o ni lati lo da ajosepo to wa laarin oun ati success
record duro.Amoran yii se Ayuba laaanfani repete nitori ni ibere 1990,Sony Music (Nigeria)gba ayuba
wole lati ko awo orin ti akole re si je
“BUBBLE”ti o jade ni odun 1991,orin yii lo so Ayuba di ilu mooka olorin, Wole
Akins ni o sig be orin naa jade,okunrin to wa leyin aseyori awo orin Shina
Peters akoko ninu itan. Orin rin Ayuba yii di orin to ni igba to si gba oju
iran awon eniyan nigbogbo igba,o si gba ami eye NIGERIAN MUSIC AWARD(NMA).Orin
yii si mu Ayuba di olokiki nla o si gba ami
eye awo orin to ni igba,ami eye olorin to ni igba,ami eye orin to ni igba,pelu
ami eye awo orin fuji to dara julo to ni igba ti o si je ami eye merin lapapo orin
naa ta koja ami o si so Ayuba dii olorin nla.Awon irinse to gbayi pelu
ohun aramada ti ayuba ni ni o mu ayipada
rere ba ise orin kiko.Ni akoko kan ninu itan,orin fuji je orin ti awon eniyan
Pataki ni ile naijiria o fibe nife si wa
di orin ti won n gba towo-tese nile ati loko.
Leyin
aseyori orin “BUBBLE”Ayuba tun gbe awo ori imiran sita ti a pen ii MR JOHNSON
JO FUN MI ti o wa labe SONY MUSIC
NIGERIA LABEL ti o sin je aseyori kiakia ni odun 1992.O tun gbe orin imiran ti
o la awon egbe ti a pe ni “BUGGIE D”ti o
si je orin to fakoyo pelu aseyori nla ti o si gba ami eye repete
lorisirisini FAME MUSIC
AWARDS(F.M.A).Won gba Ayuba si Q-BADISC RECORD COMPANY ni U.S.A ti o si fowo si
iwe adehun lati sise pelu won fun odun kan ni odun 1996
Nigba
to di 1997,o tun gbe orin fuji dub ni AGOGO MUSIC LABEL ni London,England. ni
odun 1998,o pada wa si ile naijiria ti o sit un se awo orin to laamilaaka ti o
si ni aseyori nla ni ori CORPORATE MUSIC LABEL.
Ni odun
2000,o tun gbe awo orin nla ti a pe akole re ni TURN ME ON.Orin yii fakoyo
laarin awon orin egbe re ni ile naijiria
Comments