Won kilo fawon akekoo Poli lori iwokuwo aso

Oga-agba ile eko Poli Ibadan, Ojogbon Olatunde Olubanjo Fawole, ti kilo fawon akekoo
tuntun ti won sese gba wole, paapaa awon obinrin lati yago fun wiwo aso penpe tabi eyi to
le si awon eya ara won sile.

O sekilo yii nigba to n soro nibi ibura ti won se fawon akekoo ti won gba wole ni eka Saki
lojo Isegun, Tusde, to koja.
Ojogbon Fawole tesiwaju pe awon igbimo alase ileewe ti n wa gbogbo ona lati dena iwa
abuku ohun, agbekale ofin to de iwokuwo aso fun okunrin ati obinrin si ti wa. O tesiwaju pe
o ti di eewo fun okunrin lati fi yeti seti, irun didi ti di ewo, ijiya to lagbara si wa.
O ni ile eko ohun ti to awon gbajugbaja akekoo, o si parowa fawon tuntun naa lati wo won
gege bii awokose. O parowa fun won pe iwa omoluabi, yiyago fun egbe okunkun tabi mimu
oogun oloro nikan lo le mu won saseyori.
Ninu oro tie, oludari ileewe naa, eka ti ilu Saki, Ogbeni Matthew Oladeji, ni ileewe naa ti n
se buredi, awon n sin maalu ati eja, adie ati ileese omi, eyi ti yoo mu owo wole sinu apo
ileewe, tawon akekoo yoo si fi se ise oojo.

Comments