Tisa ileewe New Horizon Islamic School fipa ba akekoo e lo po n'Ilupeju

O·loôrun nikan lo le ko ômôkunrin eni ôdun metalelogun kan, Abdukadiri Olaitan, to je
olukô nileewe alakôbere New Horizon Islamic School, yô lori esun tile-ejô Majisireeti to
wa ni Yaba ka si i lese lôjô Isegun, Tusde, ôse to kôja, pe o fipa ja ibale ômôdebinrin eni ôdun mejô kan ta a foruko bo lasiiri.
Okunrin olujejo naa to n gbe lojule kin-in-ni, laduugbo Ajisegiri, n'Ilupeju, ni a gbo
pe o huwa ti ko tôna sômodebinrin ôhun ti wôn pe lôkan lara awôn akeko ileewe alakobere
naa to fikale saduugbo Okearin, n'Ilupeju, ni ôjo kôkandinlogun, osu kejila
, ôdun
2013. Nise lo tan an lô sile e ti won ni ko fi bee jinna sagbegbe ibi tileewe yii wa, nibi taaye
yoo ti gba a daadaa lati le ba ômô yii ni nnkan pô.
Gere ti tisa yii atômô naa dele e lo ki i mole, lo ba kona fun un karakara lai tie da a ro
leemeji pe ômô ôhun kere pupo soun lôjo ori, eyi ti wôn lo sokunfa bi ômôdebinrin yii se
padanu ibale re.
Agbenuso ijoba, Inspekito Godwin Anyanwu, so ninu ôro re pe ai si itôju to peye fômô oôhun
latôdô awôn alagbato e lo fa sababi ohun to sele si i yii, o ni bo ba se pe awôn obi e mojuto o
bo ti ye ni, iru ohun to sele si i naa ko ni i waye. Bee lo bu enu ate lu iwa tolukô naa hu, eyi
to lo se lati fi tabuku ise to yan laayo gege bii eni to ye ko maa tô awôn akeko re sôna nipa
ohun to tô ati eyi to ye, sugbôn to kô lati se bee.
Esun ti wôn fi kan olujejô yii to loun ko jebi re rara lagbenusô naa sô pe o lodi sabala
ketadinlogoje ninu iwe ofin iwa ôdaran tôdun 2011, bee ni ijiya wa fun un pelu.
Ninu idajo re, Adajô-binrin Yewande Aje-Afunwa ni bo tile je pe ese ti Olaitan se yii
lagbara pupô, eyi to si tun fara pe ewôn gbere, sibe, o faaye beeli sile fun un pelu owo to to
idaji milionu naira ati oniduuro meji tawôn naa gbôdô niru owo bee lowo.
O ni ôkan ninu awôn oniduuro ôhun gbodo ni dukia olowo iyebiye niluu Eko, ko si tun je
gbajumo lawujo tabi asaaju esin, sugbôn keni keji je ibatan olujejo naa. O waa sun igbejô
mi-in sojô kejila, osôu karun-un, oôdun yii.

Comments