Nibi ifilole iwe owe, won ro awon obi lati maa ko awon omo won ni owe Yoruba

Awon agba Yoruba lati eka ijoba ati aladaani lorisiirisii ti sekilo nla fun gbogbo omo
kaaaro o o jiire lori bi owe Yoruba sôe n soônu dieôdieô, eyi to n mu akude ba awujo. Ikilo ohun
waye nibi ifilole iwe ti Amofin Oladimeji Olawuyi ko to pe ni Akojopo Eedegbaaje Owe ati
Asayan Oro Yoruba, eyi to waye ni gbongan Afe Babalola, ni Yunifasiti ijoba apapo ipinle
Eko (UNILAG).

Ninu oro akoso re, Amofin Olawuyi so o di mimo pe ibere pepe lo ye kawon obi ati oluko
ti maa ko awon omo ni owe ati asa Yoruba nitori eyi lo ran oun lowo lati ko iwe naa. O ke si
ijoba ati gbogbo awon toro kan leka imo ede lati gbaruku ti ede Yoruba ki awon nnkan iyi ti
a ni ma baa parun.
Nigba to n se atupale iwe ohun, Omowe E.T Ojo lati eka-eko imo ede ni ileewe giga ijoba
apapo ti eto naa ti waye salaye pe asipa owe po laarin awon omo Yoruba ode oni, eyi to n je
ki itumo sonu, ti opo omo kaaaro-o-o-jiire si n gbagbe orirun won. O ni alaye, ikilo ati iwa
omoluabi kun inu awon owe Yoruba, eyi si ye ko je koriya fun gbogbo eeyan lati ni imo re.
Ninu oro Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbeôsola ti Omowe Adeleke Ipaye soju fun, o
ni ijoba ko ni i fowo yepere mu asa wa, ati pe lilo tawon lo iwe owe Amofin Olawuyi ohun
ninu ‘Opon imo’ tawon gbe kale ni ohun to kere ju tawon le se lori igbelaruge ede Yoruba.
Awon omowe, asoju ijoba ati elegbejegbe lo pese sibi ifilole ohun. Die lara won ni: Akogun
Tola Adeniyi; Seneto Segun Bamgbetan, Abileko Lawal to je Aare Egbe Akomolede atawon
oloye re, Omowe Lere Adeyemi, Omowe Caleb Orimogunje, Oloye Bayo Adewakun to je
olufiloleô agba ati Oloye Funso Ogidiolu to jeô alaga eto.

Comments