Loni opo enia mo
nro pe gbogbo awa ti awa ni ipinle mefa yi Oyo, Osun, Ogun, Ondo,
Ekiti, Eko pelu ipinle Kwara to nka ara won mo ara ipinle Hausa ni o nje
Yoruba, ko ri be o, eya kan ni Yoruba nile Odua bi Ekiti se je eya kan
ti Egba naa je eya kan be pelu ni Awori naa je Eya kan pelu, koda awon
Egun to wa ni badagiri leko ko ba awon omo Odua tan rara (e lo wo Itan
Badagiri).
Ki oro ba le ye wa dada e je ka salaye ohun to nje eya fun wa, eya ni ohun to ya lati ara odidi nkan kakari agbaye si ni eya po si, Odua ni baba nla gbogbo eya to wa ipinle mefa yi pelu Kwara sugbon gbogbo wa koni Yoruba. Eya to ya lara Odua le ni merindilogun ti olukulu si mo baba nla re bi eya Yoruba se mo pe Oranmiyan ni baba nla won. Odua lo so gbogbo won po akojopo awon eya yi lo wa nje orilede iyen ni ibi ti won ti nso ede to sunmorawon, iyato diedie yio mo wa nibi ede siso latari alafo ona jinjin to wa larin won, sugbon ti enia ba fi ara ba le yio si gbo ohun ti ede kan nba ede keji so
Comments