TANI ODUDUWA?

Odùduwà Bí abá porí akoni, áafidà halè gààràgà, táabá porí èya Yorùbá, dandan ni kí á sòrò débi eni tó jé babańlá won, Ìyen Odùduwà á tìe wòrò.
Ìtàn méjì gbógì ló sòrò tó seé gbámú nípa ibi tí Odùduwà ti wá, àkókó ìtàn náà ni ìtàn tó sórò nípa tí Odùduwà se wá láti wáá gba isé tí Olódùmarè kókó rán Obàtálá se.
Olódùmarè fún Oduduwa ní àwon nìkan máàmú ken, èyí tó mú wá láti wáá lo, ómú èwòn wá èyí tó fi rò wá, àti àkùko adìye èyí tó tan yèpè tó mú wá kálè, tí ìyàngbe ilè fi jáde.
Ó wá mú ìgbá dání, èyí tó gbìn àti alágemo tó lo wòó bóyá ilè náà ti gbe.
Ó dùduwà yìí ló wá dásèé gbogbo èdá tó wà lórí ilè ayé, ibi tó sì rò sí ni Ilé-Ifè, Ibi tí wón so pé ojúmó ti ń mó wá.
Nítóri náà, gégé bíi ìtàn yìí se so, Odùduwà kìíníkàn ńse bàbá ńlá Yorùbá nìkan, Sùgbón bàbá ńlá gbogbo aráyé, nígbà tí Ifè kìí níkàn ńse orírun Yorùbá nìkan, sùgbón orísun gbogbo èdá.
Ìtàn lejì so pé Mékà ni eni tí a mò sí Odùduwà ti wá, ìwà ìbòrìsà reè sì ló gbée kúrò ní Mékà.
Ìtàn yìí so pé Ìjà bé sílè láàrín-ín àwon elésìn musùlùmí àti àwon abòrìsà, ti Odùduwà je olórí won, inú ìjà yìí ni Lámúrúdu, eni tí ó jé bàbá Odùduwà kú sí, èyìn èyí ni Odùduwà gbéra kúrò ní Mékà tó sì wá tèdó sí Ilé-Ifè.
Ìtàn fi yé wa pé, Odùduwà bá àwon ènìyàn kan ní Ile-Ifè, àwon ènìyàn yìí ni Odùduwà bá fìjà peéta, tí ó sì borí won nígbèyìn gbéyìn ó bo rí won, ó sì wáá doba won.
Ìtàn yìí jé kí á mò wípé odùduwà ló mú ètò ìsàláóso wá sí Ilé-Ifè, èyí tó gbé wá láti ìlú Mékà.
Nígbà tí Odùduwà dàgbà títí ó wà fún àwon omo rè ní ade, ósì fún àwon kan ní ìlèkè. Àwon omo Odùduwà wònyín ló te àwon ìlú dó káàkiri ilè Yorùbá.

Comments