ITAN EYE ODIDERE

Eye Odidere naa ni Yoruba npe ni eye Aiye-kooto, eye to rewa ni eye Odidere ko si ilu ti enia le de ni’le Yoruba ti enia o ni ri enikan o kere ju ti yio ni eye yi nile. Sugbon opo awon to ni eye yi nile papa ko kiyesi awon emo to wa lara eye Odidere won kan mo pe o mo nsoro ni atipe Ikode (iye idi) re je eyi ti won mo ri ta, sugbon ti opo ba mo nipa eye ti won gbe sinu ile won o ni fe danwo lasa. Sugbon o eye Odidere kiise enia ni ijanba Kankan nigbati o ba ti de ile koda omode lasan le mo fi sere lai sewu.

1.       Eye Odidere ki fi ese kan ile tabi erupe
2.       Inu iho igi lo mo nye eyin si
3.       Ti ogomo ba kan eyin Odidere yio lana
4.       Enia o le fi oju kan eyin Odidere koju naa mo fo
5.       Owo ni ikode Odidere
6.       Owo ni igbe Odidere
7.       Odidere mo nsoro bi enia
Awon emo ara eye Odidere ti  un so fun wa niyi, Odidere kii fi ese kanle tabi erupe lojo ti o ba fi ese kanle tabi erupe ni ko tun fo mo laye, inu iho igi lo mo nye eyin si nitori bi enia ba fi oju kan eyin eye Odidere oju naa yio fo lailai ko si ohun to le la oju naa, ti awon ode ba fe mo pe eye Odidere lo nye eyin sinu iho igi kan won o lo mu Ogomo (mariwo ope tuntun to sese yo) won wa te bo inu iho igi naa, bi o ba se nkan eyin Odidere ni yio gba ina lara ti ina naa yio si jo de oke, won o wa mo so igbati yio pamo ti won ba ti mo pe o ti pamo won o so akara kengbe mo ara ogomo ti awon omo eye Odidere ba ti ri akara yi won yio so mo eni to wa ni ita yio wa mo fa bo nita, bi won ba ti mu jade ese re ni won o koko fi lele ko tun le fo mo lailai.
Looto enia le ri eyin Odidere to je ti awon Oibo sugbon ti enia ba wo eye Odidere ti Oibo ati Yoruba dada yio ri pe iyato nla lo wa larin tiwa ati Oibo, nitorina ki enia ma lo ro pe enia le fi oju kan eyin Odidere Yoruba. Ikilo ni fun eni ba fe gbo.
Eyin Odidere ni won mo nfi sinu ade laye atijo idi niyi ti Oba ati enia o gbodo fi si oju wo inu ade. Owo ni ikode Odidere ikode ni  iye to je iru re pupa ni ikode Odidere keke lo mo nri kii  gun beni si ni igbe Odidere naa tun je owo. Awon Yoruba mo nlo iye ati igbe Odidere fun opo isegun, awon miran ti e mo nlo odidi eye yi. Olori emo eye yi wa ni oro to mo nso, oro da lenu eye yi ti enia yio fi gbo ohun to nso bi igba ti enia ba n sufe ni oro re, bi enia ba wa enia wa nigbati enia ko sini ni ile Odidere yio jise fun oluware to ba de. nkan asiri tabi oro asiri ko se so loju eye yio nitori ko ni se bi enipe ohun ri yin sugbon o ro lorun ko fi wakati kan ro ejo naa fun gbogbo ara ile lati ara oro re ni Yoruba se npe eye Pataki yi ni Aye-Kooto.

Comments