Yorùbá jẹ ọkan lara awọn ede mẹrin ti o se itẹwọgba ni Naijeria o si jẹ ọkan lara awọn ẹka -ede ti Naija-Kongo. Bi i miliọnu mejilelogun eniyan ni n sọ ede naa ni iwọ oorun-mọ-guusu Naijeria, orilẹ ede
Benin, Togo, Ilu Ọba (UK), ati ni Amẹrika.
A kọ Yoruba fun ìgbà akọkọ ni bii igba ọdun diẹ sẹhin. Awọn atẹjade akọkọ lori Yoruba ni awọn iwe idanilẹkọ pelebe-pelebe ti a ti ọwọ John Raban kọ ni ọdun 1830 si 1832. Ẹni ti o ko ipa ti o tobi julọ si imọ-ẹkọ Yoruba ni. Bisọọbu Ajayi (Samuel) Crowther (1806 si 1891), ẹni ti o kẹkọọ nipa diẹ ninu awọn ede ti a n sọ ni Naijeria, eyi ti Yoruba jẹ ọkan ninu wọn, o kọwe, o si tun ̣se titumọ diẹ ninu wọn. Crowther tun jẹ Bisọọbu onigbagbọ akọkọ ti orirun rẹ jẹ Ìwọ-Oorun Afirika. Akọtọ Yoruba akọkọ jade ni nnkan bi i ọdun 1850, biotilẹjẹpe o ti la orisirisi iyipada kọja lati igba naa.
Comments